Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

مَريَم

مَريَم is chapter 19 of the Quran and has 98 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

98 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 19
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

كٓهيعٓصٓ

Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

ذِكۡرُ رَحۡمَتِ رَبِّكَ عَبۡدَهُۥ زَكَرِيَّآ

(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀ (Ànábì) Zakariyyā.

إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥ نِدَآءً خَفِيّٗا

(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.

قَالَ رَبِّ إِنِّي وَهَنَ ٱلۡعَظۡمُ مِنِّي وَٱشۡتَعَلَ ٱلرَّأۡسُ شَيۡبٗا وَلَمۡ أَكُنۢ بِدُعَآئِكَ رَبِّ شَقِيّٗا

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.

وَإِنِّي خِفۡتُ ٱلۡمَوَٰلِيَ مِن وَرَآءِي وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا فَهَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا

Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,