Skip to content

Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa"

Lati ọdọ Salamah ọmọ Al-hakwa'u- ki Ọlọhun yọnu si i-:

Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa", nnkan ko kọdi rẹ afi igberaga, o sọ pe: Ko si lee gbe e si ẹnu rẹ mọ.

أَنَّ رَجُلًا أَكَلَ عِنْدَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ بِشِمَالِهِ، فَقَالَ: «كُلْ بِيَمِينِكَ»، قَالَ: لَا أَسْتَطِيعُ، قَالَ: «لَا اسْتَطَعْتَ»، مَا مَنَعَهُ إِلَّا الْكِبْرُ، قَالَ: فَمَا رَفَعَهَا إِلَى فِيهِ.

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ri arakunrin kan ti o n jẹun pẹlu ọwọ rẹ osi, o wa pa a láṣẹ lati jẹun pẹlu ọwọ rẹ ọtun, Arakunrin naa wa da a lohun ni ti igberaga ati irọ pe oun ko ni ikapa! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹbi le e pe ki wọn ṣe jijẹ pẹlu ọwọ ọtun leewọ fun un, Ọlọhun ba gba adura Anabi Rẹ pe ki ọwọ ọtun rẹ rọ, ko si lee gbe e si ẹnu rẹ lẹyin ìyẹn pẹlu oúnjẹ tabi nǹkan mimu.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Jijẹ dandan jijẹun pẹlu ọwọ ọtun, ati jijẹ eewọ jijẹun pẹlu ọwọ osi.

Ṣíṣe igberaga nibi titẹle awọn ofin Sharia maa n mu ẹni ti o ba ṣe lẹtọọ si iya.

Apọnle Ọlọhun fun Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu gbigba adura rẹ.

Ṣíṣe pipaṣẹ pẹlu daadaa lofin ati kikọ kuro nibi ibajẹ ni gbogbo isẹsi koda nibi isẹsi jijẹ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (3/ 1599) (2021).

Àlékún (6)

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (1/ 239).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (1/ 183).

كنوز رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (3/ 396).