Skip to content

Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:

Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa”, wọn tun bi i leere nipa nnkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ ina julọ, o sọ pe: “Ẹnu ati Abẹ”.

سُئِلَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَنْ أَكْثَرِ مَا يُدْخِلُ النَّاسَ الْجَنَّةَ، فَقَالَ: «تَقْوَى اللهِ وَحُسْنُ الْخُلُقِ»، وَسُئِلَ عَنْ أَكْثَرِ مَا يُدْخِلُ النَّاسَ النَّارَ فَقَالَ: «الْفَمُ وَالْفَرْجُ».

Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
O daa, o si ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu èèyàn wọ alujanna méjì ni, àwọn naa ni: Ipaya Ọlọhun ati iwa dáadáa. Ìpayà Ọlọhun: Oun ni ki o fi aabo si aarin rẹ ati iya Ọlọhun, pẹ̀lú ṣíṣe àwọn nǹkan ti O pàṣẹ lati ṣe, ati jíjìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀. Iwa dáadáa: O maa jẹ pẹlu títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ki èèyàn ma jẹ ki suta kan ẹlòmíràn. Eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu awọn èèyàn wọ ina meji ni, àwọn naa ni: Ahọn ati Abẹ́. Lara àwọn ẹṣẹ ahọ́n ni: Irọ́, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, òfófó, ati awọn mìíràn. Lara àwọn ẹṣẹ abẹ́ ni: Ṣìná, ati ibalopọ láàrin ọkùnrin si ọkùnrin, ati awọn mìíràn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Wiwọ alujanna ni àwọn okùnfà ti o nii ṣe pẹ̀lú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ninu wọn ni: Ibẹru Rẹ, ati awọn okunfa ti o nii ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn, ninu wọn ni: Ìwà dáadáa.

Ewu ahọn fun ẹni tí ó ni ín, ati pe o wa ninu awọn okùnfà wíwọ iná.

Ewu ìfẹ́-adùn ati awọn ìwà ibajẹ fun ọmọniyan, ati pe wọn wa ninu awọn okùnfà ti o pọ julọ lati wọ iná .

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sunanu ti Tirmidhiy (3/ 536) (2004).

Tira Sunanu ti Ọmọ Maajah (5/ 318) (4246).

Tira Musnad ti Ahmad (13/ 287) (7907).

Àlékún (8)

توضيح الأحكام من بلوغ المرام.

للبسام (7/ 509).

منحة العلام في شرح بلوغ المرام.

لعبد الله الفوزان (10/ 369).

فتح ذي الجلال والإكرام.

لابن عثيمين (6/ 453).

سبل السلام بشرح بلوغ المرام.

للصنعاني (2/ 696).