Skip to content
آل عِمران /

Ẹsẹ 110

3 : 110

Ẹsẹ 110 of آل عِمران (3 : 110). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

آل عِمران Àwọn Ẹsẹ 200
3 : 110

كُنتُمۡ خَيۡرَ أُمَّةٍ أُخۡرِجَتۡ لِلنَّاسِ تَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَتَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِۗ وَلَوۡ ءَامَنَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۚ مِّنۡهُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ

Ẹ jẹ́ ìjọ tó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.

Explanation & meanings · 1
  1. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìpèpè Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dé bá, tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì gba ’Islām.