“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.
Lati ọdọ Uthman ọmọ Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.
«مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ حَتَّى تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظْفَارِهِ».
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala pẹlu ṣíṣe àkíyèsí awọn sunna aluwala ati awọn ẹkọ rẹ, iyẹn maa wa ninu awọn okunfa pipa awọn ẹṣẹ rẹ ati pipa àṣìṣe rẹ, titi awọn ẹṣẹ rẹ yoo fi jade labẹ awọn èékánná ọwọ rẹ mejeeji ati ti ẹsẹ rẹ méjèèjì.
...:
Ṣisẹnilojukokoro lori ìní akolekan kikọ aluwala ati sunnah rẹ ati awọn ẹkọ rẹ, ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu ìyẹn.
Ọla ti o n bẹ fun aluwala, ati pe o jẹ ipa ẹṣẹ keekeeke rẹ, sugbọn awọn ẹṣẹ ńlá, ironupiwada jẹ dandan lati pa wọn rẹ.
Majẹmu jijade awọn àṣìṣe ni pipe aluwala ati ṣíṣe e laisi alebu kankan gẹgẹ bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ṣàlàyé rẹ.
Pipa ẹṣẹ rẹ ninu hadisi yii jẹ nnkan ti a de pẹlu ijina si awọn ẹṣẹ ńlá ati ironupiwada kuro nibẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pé: (Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá tí A kọ̀ fun yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fun yín) (An-Nisa: 31).
Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 216) (245).
Àlékún (6)
شرح رياض الصالحين.
لابن عثيمين (5/ 9).
نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.
لمصطفى الخِن وغيره (2/ 763).
بهجة الناظرين.
سليم الهلالي (2/ 247).
A tọ́ka sí nínú àwọn ìwé
8 Àwọn ÌwéÀlékún (7)
- المختصر المفيد للمسلم(من توضأ فأحسن الوضوء خرجت خطاياه من جسده حتَّى تَخْرُجَ مِنْ تحتِ أَظفارِهِ)
- المنتقى من المتجر الرابح في ثواب العمل الصالح - المعتمدالمنتقى من المتجر الرابح في ثواب العمل الصالح“من توضأ فأحسن الوضوء خرجت خطاياه من جسده حتى تخرج من تحت أظفاره”.
- خطب تعظيم قدر الصلاة"مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ، حَتَّى تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظْفَارِهِ" رواه مسلم [26]،
- رياض الصالحينرياض الصالحين مع فوائد وهدايات - 5«مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الوُضُوءَ، خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ حَتَّىٰ تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظفارِه».
- مجموعة زاد الحديث(3)1«من توضَّأ فأحْسَنَ الوُضُوءَ خَرَجَت خطاياه من جَسَدِهِ حتى تخرجَ من تحتِ أظفارِهِ»
- مشروع منهاج زادكزادك 1 طالب«مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ، حَتَّى تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظْفَارِهِ»
- من الأحكام الفقهية في الطهارة والصلاة والجنائز«مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ، حَتَّى تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظْفَارِهِ»