Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

النَّجم

النَّجم is chapter 53 of the Quran and has 62 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

62 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 53
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلنَّجۡمِ إِذَا هَوَىٰ

Allāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.

Explanation & meanings · 1
  1. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, Allāhu fi ìràwọ̀ nígbà tí ó bá wálẹ̀ (wọ̀ọ̀kùn ní ìdájí) búra. Àmọ́ ìtúmọ̀ àkọ́kọ́ ló súnmọ́ jùlọ ní ìbámu sí sàkánì rẹ̀ pẹ̀lú àwọn āyah tí ó tẹ̀lé e. Wòóore! Wọ́n ń pe gbólóhùn ẹyọ kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān ní “an-najm”. Wọ́n sì ń pe ìràwọ̀ ní “an-najm”. Kódà “ìtàkùn” náà ń jẹ́ “an-najm” nínú èdè Lárúbáwá.(Tafsīr ’Adwā’ul-bayān)

مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمۡ وَمَا غَوَىٰ

Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.

Explanation & meanings · 1
  1. Ènìyàn “dọlla” nígbà tí ó bá fi àìmọ̀kan sẹ̀sìn. Ènìyàn tí kò tẹ̀lé ìmọ̀ tí ó mọ̀, òun ló “gawā”.

وَمَا يَنطِقُ عَنِ ٱلۡهَوَىٰٓ

Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.

إِنۡ هُوَ إِلَّا وَحۡيٞ يُوحَىٰ

Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ni pé, ìmísí mímọ́ ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.

عَلَّمَهُۥ شَدِيدُ ٱلۡقُوَىٰ

Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).