Skip to content

Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom

Lati ọdọ Thaoban- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n wa aforijin lẹẹmẹta, o maa sọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom”, Al-Waleed sọ pé: Mo sọ fun Al-‘Aozaa’iy: Bawo ni a ṣe maa n wa àforíjìn? O sọ pe: Waa sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah.

كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ إِذَا انْصَرَفَ مِنْ صَلَاتِهِ اسْتَغْفَرَ ثَلَاثًا، وَقَالَ: «اللَّهُمَّ أَنْتَ السَّلَامُ، وَمِنْكَ السَّلَامُ، تَبَارَكْتَ ذَا الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ»، قَالَ الْوَلِيدُ: فَقُلْتُ لِلْأَوْزَاعِيِّ: كَيْفَ الْاسْتِغْفَارُ؟ قَالَ: تَقُولُ: أَسْتَغْفِرُ اللهَ، أَسْتَغْفِرُ اللهَ.

Muslim ni ọ gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah, Astagfirullah. Lẹyin naa o maa gbe Oluwa rẹ tobi pẹlu sisọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikrọọm” Ọlọhun ni Ọba Àlàáfíà ti O pe nibi awọn iroyin Rẹ, ti a fọmọ kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku, ti o si n wa lílà lọdọ Rẹ kuro nibi awọn aburu aye ati ọrun ti ko ki n ṣe lọdọ ẹni ti o yatọ si I, Oun- mimọ ni fun Un- ni daadaa Rẹ pọ ni aye ati ọrun, Ẹni ti O ni titobi ati daadaa.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lẹyin irun ati didunni mọ ọn.

Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lati wa pipe adinku to wa nibi ijọsin ati lati dí àáyẹ fun itẹle ati aṣeeto to wa nibẹ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 414) (591).

Àlékún (6)

مرعاة المفاتيح شرح مشكاة المصابيح.

لعبيد الله المباركفوري (3/ 317).

سبل السلام.

للصنعاني (1/ 294).

توضيح الأحكام مِن بلوغ المرام.

لعبد الله البسام (2/ 301).