Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الأحزَاب

الأحزَاب is chapter 33 of the Quran and has 73 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

73 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 33
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ ٱتَّقِ ٱللَّهَ وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا

Ìwọ Ànábì, bẹ̀rù Allāhu. Má sì tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا

Tẹ̀lé ohun tí A ń mú wá fún ọ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا

Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.

مَّا جَعَلَ ٱللَّهُ لِرَجُلٖ مِّن قَلۡبَيۡنِ فِي جَوۡفِهِۦۚ وَمَا جَعَلَ أَزۡوَٰجَكُمُ ٱلَّٰٓـِٔي تُظَٰهِرُونَ مِنۡهُنَّ أُمَّهَٰتِكُمۡۚ وَمَا جَعَلَ أَدۡعِيَآءَكُمۡ أَبۡنَآءَكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ قَوۡلُكُم بِأَفۡوَٰهِكُمۡۖ وَٱللَّهُ يَقُولُ ٱلۡحَقَّ وَهُوَ يَهۡدِي ٱلسَّبِيلَ

Allāhu kò fún ènìyàn kan ní ọkàn méjì nínú ikùn rẹ̀. (Allāhu) kò sì sọ àwọn ìyàwó yín, tí ẹ̀ ń fi ẹ̀yìn wọn wé ẹ̀yìn ìyá yín, di ìyá yín. Àti pé (Allāhu) kò sọ àwọn ọmọ-ọlọ́mọ tí ẹ̀ ń pè ní ọmọ yín di ọmọ yín. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ẹnu yín. Allāhu ń sọ òdodo. Àti pé Òun l’Ó ń fi (ẹ̀dá) mọ̀nà.

ٱدۡعُوهُمۡ لِأٓبَآئِهِمۡ هُوَ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِۚ فَإِن لَّمۡ تَعۡلَمُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَمَوَٰلِيكُمۡۚ وَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٞ فِيمَآ أَخۡطَأۡتُم بِهِۦ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتۡ قُلُوبُكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمًا

Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ kò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín níbi ohun tí ẹ ti ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Explanation & meanings · 1
  1. Àṣẹ pípe ẹrú pẹ̀lú orúkọ bàbá rẹ̀, tí fífi orúkọ olówó-ẹrú pe ẹrú kò sì dára, èyí ti fi hàn kedere pé, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún obìnrin láti fi orúkọ ọkọ rẹ̀ pààrọ̀ orúkọ bàbá rẹ̀.