33 : 9
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ جَآءَتۡكُمۡ جُنُودٞ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا وَجُنُودٗا لَّمۡ تَرَوۡهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرًا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ kò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Explanation & meanings · 1
- Ọmọ ogun oníjọ ni àwọn ọmọ ogun ìjọ mẹ́ta kan tó para pọ̀ lórí ìjọ ọmọ ogun Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - : ìjọ ọmọ ogun Ƙuraeṣi, ìjọ ọmọ ogun Gatfān àti ìjọ ọmọ ogun Yẹhudi tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Nadīr.