33 : 5
ٱدۡعُوهُمۡ لِأٓبَآئِهِمۡ هُوَ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِۚ فَإِن لَّمۡ تَعۡلَمُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَمَوَٰلِيكُمۡۚ وَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٞ فِيمَآ أَخۡطَأۡتُم بِهِۦ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتۡ قُلُوبُكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمًا
Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ kò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín níbi ohun tí ẹ ti ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Explanation & meanings · 1
- Àṣẹ pípe ẹrú pẹ̀lú orúkọ bàbá rẹ̀, tí fífi orúkọ olówó-ẹrú pe ẹrú kò sì dára, èyí ti fi hàn kedere pé, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún obìnrin láti fi orúkọ ọkọ rẹ̀ pààrọ̀ orúkọ bàbá rẹ̀.