Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

السَّجدة

السَّجدة is chapter 32 of the Quran and has 30 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

30 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 32
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓمٓ

’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَا رَيۡبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۚ بَلۡ هُوَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٖ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:46.

ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ مَا لَكُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِيّٖ وَلَا شَفِيعٍۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fún yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?

يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ يَعۡرُجُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥٓ أَلۡفَ سَنَةٖ مِّمَّا تَعُدُّونَ

Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:47.