Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

النَّحل

النَّحل is chapter 16 of the Quran and has 128 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

128 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 16
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

أَتَىٰٓ أَمۡرُ ٱللَّهِ فَلَا تَسۡتَعۡجِلُوهُۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

يُنَزِّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ بِٱلرُّوحِ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرُوٓاْ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱتَّقُونِ

(Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”

خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ تَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ

Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde).

وَٱلۡأَنۡعَٰمَ خَلَقَهَاۖ لَكُمۡ فِيهَا دِفۡءٞ وَمَنَٰفِعُ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ

Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn (fún yín). Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fún yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn.