Skip to content
النَّحل /

Ẹsẹ 44

16 : 44

Ẹsẹ 44 of النَّحل (16 : 44). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

النَّحل Àwọn Ẹsẹ 128
Súrà · النَّحل
Yorùbá · Mikail
16 : 44

بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِۗ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلذِّكۡرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيۡهِمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ

(A fi) àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Orúkọ tí wọ́n ń pe àlàyé tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe lórí al-Ƙur’ān ni “hadīth nabawiy” tàbí “sunnatu-rrọsūl” - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Ìmísí ni òhun náà nítorí pé, kì í fi ìfẹ́-inú rẹ̀ sọ̀rọ̀.