Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الحِجر

الحِجر is chapter 15 of the Quran and has 99 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

99 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 15
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ وَقُرۡءَانٖ مُّبِينٖ

’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.) Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

رُّبَمَا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ كَانُواْ مُسۡلِمِينَ

Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).

ذَرۡهُمۡ يَأۡكُلُواْ وَيَتَمَتَّعُواْ وَيُلۡهِهِمُ ٱلۡأَمَلُۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ

Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

وَمَآ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٞ مَّعۡلُومٞ

A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.

مَّا تَسۡبِقُ مِنۡ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ

Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.