Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الفَتح

الفَتح is chapter 48 of the Quran and has 29 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

29 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 48
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِنَّا فَتَحۡنَا لَكَ فَتۡحٗا مُّبِينٗا

Dájúdájú Àwa ṣẹ́gun fún ọ ní ìṣẹ́gun tó fojú hàn

لِّيَغۡفِرَ لَكَ ٱللَّهُ مَا تَقَدَّمَ مِن ذَنۢبِكَ وَمَا تَأَخَّرَ وَيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَيَهۡدِيَكَ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا

nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀), àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām),

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.

وَيَنصُرَكَ ٱللَّهُ نَصۡرًا عَزِيزًا

àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe tó lágbára.

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ لِيَزۡدَادُوٓاْ إِيمَٰنٗا مَّعَ إِيمَٰنِهِمۡۗ وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا

Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

لِّيُدۡخِلَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَيُكَفِّرَ عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عِندَ ٱللَّهِ فَوۡزًا عَظِيمٗا

(Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn) nítorí kí Ó lè mú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀, olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀, àti nítorí kí Ó lè pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ èrèǹjẹ ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu.