Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الشُّورى

الشُّورى is chapter 42 of the Quran and has 53 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

53 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 42
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

عٓسٓقٓ

‘Aēn sīn ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

كَذَٰلِكَ يُوحِيٓ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ.

Explanation & meanings · 1
  1. È é ti ṣe tí Allāhu lẹ́yìn tí Ó sọ pé “Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ.” kò fi kún un pé, “àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ”? Ìdí ni pé, Allāhu ti fi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe òpin àwọn arímìísígbà “kātamu-nnabiyyīn”. Ẹ wo sūrah al-’Ahzāb; 33:40.

لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ

TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ó ga, Ó tóbi.

تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِن فَوۡقِهِنَّۚ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Sánmọ̀ fẹ́ẹ̀ fàya láti òkè wọn (nípa títóbi Allāhu). Àwọn mọlāika sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa wọn. Wọ́n sì ńtọrọ àforíjìn fún àwọn tó wà lórí ilẹ̀. Gbọ́, dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.