Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الرُّوم

الرُّوم is chapter 30 of the Quran and has 60 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

60 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 30
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓمٓ

’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

غُلِبَتِ ٱلرُّومُ

Wọ́n ṣẹ́gun Rōmu

Explanation & meanings · 1
  1. Àwọn ará ilẹ̀ Fārisi (ìyẹn ̓Irān)

فِيٓ أَدۡنَى ٱلۡأَرۡضِ وَهُم مِّنۢ بَعۡدِ غَلَبِهِمۡ سَيَغۡلِبُونَ

ní àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá). Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn

Explanation & meanings · 1
  1. Ìyẹn ní ilẹ̀ Siria, ‘Irāƙ, Jọdan àti Palẹstin.

فِي بِضۡعِ سِنِينَۗ لِلَّهِ ٱلۡأَمۡرُ مِن قَبۡلُ وَمِنۢ بَعۡدُۚ وَيَوۡمَئِذٖ يَفۡرَحُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ

ní ọdún díẹ̀ (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣáájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú

بِنَصۡرِ ٱللَّهِۚ يَنصُرُ مَن يَشَآءُۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ

sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.