Skip to content
الرُّوم /

Ẹsẹ 26

30 : 26
الرُّوم Àwọn Ẹsẹ 60
Súrà · الرُّوم
Yorùbá · Mikail
30 : 26

وَلَهُۥ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ كُلّٞ لَّهُۥ قَٰنِتُونَ

TiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Āyah yìí jọ sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49. Àṣẹ méjì ló wà lórí ẹ̀dá. Àṣẹ àdámọ́ àti àṣẹ ìjọ́sìn. Àṣẹ àdámọ́ ló jẹmọ́ wíwá sáyé, lílọ sọ́run àti gbogbo ohun tí ọmọnìyàn kò lè ríbi yẹ̀ ẹ́ sí bí ebi, òǹgbẹ, oorun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwọ̀nyẹn ni àṣẹ Allāhu lára ẹnì kọ̀ọ̀kan, yálà onígbàgbọ́ òdodo tàbí aláìgbàgbọ́. Àmọ́ ní ti àṣẹ ìjọ́sìn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan ló ń tẹ̀lé àṣẹ Allāhu lórí rẹ̀. Ní ti àwọn aláìgbàgbọ́, àṣẹ aṣ-ṣaetọ̄n àti àṣẹ ìfẹ́-inú wọn ni wọ́n ń tẹ̀lé.