Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

العَنكبُوت

العَنكبُوت is chapter 29 of the Quran and has 69 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

69 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 29
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓمٓ

’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

أَحَسِبَ ٱلنَّاسُ أَن يُتۡرَكُوٓاْ أَن يَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا وَهُمۡ لَا يُفۡتَنُونَ

Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò?

وَلَقَدۡ فَتَنَّا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَلَيَعۡلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْ وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱلۡكَٰذِبِينَ

A kúkú ti dán àwọn tó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́.

أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَسۡبِقُونَاۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ

Àbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.

مَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ ٱللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ لَأٓتٖۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.