32 : 20
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فَسَقُواْ فَمَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُۖ كُلَّمَآ أَرَادُوٓاْ أَن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَآ أُعِيدُواْ فِيهَا وَقِيلَ لَهُمۡ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Ní ti àwọn tó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”
Explanation & meanings · 1
- Āyah yìí dúró sórí àwọn kèfèrí àti munāfiki, kì í ṣe mùsùlùmí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí ó tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.