Skip to content

Obinrin ti ẹjẹ ibimọ n da lara rẹ, njẹ yoo jokoo fun ogoji ọjọ ti ko nii kirun tabi gba awẹ, tabi ohun ti a maa woye si ni dida ẹjẹ rẹ, gbogbo igba ti o ba ti da, yoo mọra, yoo si kirun? Ati pe ki ni akoko ti o kere julọ fun imọra?

السؤال

Ibeere akọkọ:

Obinrin ti ẹjẹ ibimọ n da lara rẹ, njẹ yoo jokoo fun ogoji ọjọ ti ko nii kirun tabi gba awẹ, tabi ohun ti a maa woye si ni dida ẹjẹ rẹ, gbogbo igba ti o ba ti da, yoo mọra, yoo si kirun? Ati pe ki ni akoko ti o kere julọ fun imọra?

س5: المرأة النّفساء هل تجلس أربعين يومًا لا تصلّي ولا تصوم، أو العبرة بانقطاع الدم عنها، فمتى انقطع تطهرت وصلت؟ وما أقلّ مدةٍ للطّهر؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Ẹni ti ẹjẹ ibimọ n da lara rẹ ko si asiko kan ti o ni aala fun un, bi ko ṣe pe gbogbo igba ti ẹjẹ naa ba ti n bẹ yoo jokoo, ti ko nii kirun, ko nii gba awẹ, ọkọ rẹ ko si nii sunmọ ọn

Ti o ba ri mimọ- koda ko jẹ ṣiwaju ogoji ọjọ-, ko da ki o ma jokoo afi fun ọjọ mewaa tabi ọjọ márùn-ún- dajudaju yoo kirun, yoo gba awẹ, ọkọ rẹ yoo ba a lopọ, ko si ẹṣẹ nibi ìyẹn-

Nnkan ti o jẹ koko ni pe dajudaju ẹjẹ ibimọ jẹ alamọri kan ti a maa n mọ ọn lara, ti awọn idajọ n so pọ mọ bibẹ rẹ ati aisi rẹ, gbogbo igba ti o ba ti n bẹ, awọn idajọ rẹ yoo maa fi ẹsẹ rinlẹ, gbogbo igba ti o ba ti mọra kuro nibẹ yoo bọ kúrò nibi awọn ìdájọ́ rẹ.

Ṣugbọn ti o ba ju ọgọ́ta ọjọ lọ, yoo di ẹni ti ẹjẹ awaada n da lara rẹ, yoo jokoo ni odiwọn ohun tí ó bá ṣe déédéé nǹkan oṣù rẹ sọ́, lẹyin naa yoo wẹ, yoo si kirun

ﺟ5: النّفساء ليس لها وقتٌ محدودٌ، بل متى كان الدم موجودًا جلست، ولم تصلّ، ولم تصم، ولم يجامعها زوجها.

وإذا رأت الطّهر -ولو قبل الأربعين، ولو لم تجلس إلا عشرة أيامٍ أو خمسة أيامٍ- فإنها تصلّي، وتصوم، ويجامعها زوجها، ولا حرج في ذلك.

والمهمّ أن النّفاس أمرٌ محسوسٌ، تتعلق الأحكام بوجوده أو عدمه، فمتى كان موجودًا ثبتت أحكامه، ومتى تطهرت منه تخلت من أحكامه.

لكن لو زاد على السّتّين يومًا فإنها تكون مستحاضةً، تجلس ما وافق عادة حيضها فقط، ثم تغتسل، وتصلّي.