Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

النَّاس

النَّاس is chapter 114 of the Quran and has 6 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

6 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 114
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ

Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,

مَلِكِ ٱلنَّاسِ

Ọba àwọn ènìyàn,

إِلَٰهِ ٱلنَّاسِ

Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,

Explanation & meanings · 1
  1. Ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun àwọn ènìyàn” ni pé, Ẹni tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, tí wọn kò sì gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀.

مِن شَرِّ ٱلۡوَسۡوَاسِ ٱلۡخَنَّاسِ

níbi aburú (aṣ-Ṣaetọ̄n) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu).

Explanation & meanings · 1
  1. Ọ̀kan pàtàkì nínú àǹfààní àti oore tí ó wà nínú ath-thikār ṣíṣe ni pé, aṣ-Ṣaetọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóò máa sá sẹ́yìn fún ẹni tí ó bá ń ṣe ath-thikār ní gbogbo ìgbà.

ٱلَّذِي يُوَسۡوِسُ فِي صُدُورِ ٱلنَّاسِ

(aṣ-Ṣaetọ̄n ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.