Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الحَاقة

الحَاقة is chapter 69 of the Quran and has 52 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

52 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 69
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱلۡحَآقَّةُ

Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!

مَا ٱلۡحَآقَّةُ

Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ

Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.

Explanation & meanings · 1
  1. Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà àti Ajámọláyà bí àrá.

فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ

Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.