Skip to content
المَائدة /

Ẹsẹ 116

5 : 116

Ẹsẹ 116 of المَائدة (5 : 116). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

المَائدة Àwọn Ẹsẹ 120
Súrà · المَائدة
Yorùbá · Mikail
5 : 116

وَإِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ءَأَنتَ قُلۡتَ لِلنَّاسِ ٱتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَٰهَيۡنِ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ مَا يَكُونُ لِيٓ أَنۡ أَقُولَ مَا لَيۡسَ لِي بِحَقٍّۚ إِن كُنتُ قُلۡتُهُۥ فَقَدۡ عَلِمۡتَهُۥۚ تَعۡلَمُ مَا فِي نَفۡسِي وَلَآ أَعۡلَمُ مَا فِي نَفۡسِكَۚ إِنَّكَ أَنتَ عَلَّٰمُ ٱلۡغُيُوبِ

(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l’o sọ fún àwọn ènìyàn pé: “Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?” Ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. Èmi ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.