Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

صٓ

صٓ is chapter 38 of the Quran and has 88 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

88 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 38
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

صٓۚ وَٱلۡقُرۡءَانِ ذِي ٱلذِّكۡرِ

Sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.) Allāhu fi al-Ƙur’ān tí ó kún fún ìrántí bura.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي عِزَّةٖ وَشِقَاقٖ

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo).

كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّن قَرۡنٖ فَنَادَواْ وَّلَاتَ حِينَ مَنَاصٖ

Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) nígbà tí kò sí ibùsásí kan.

وَعَجِبُوٓاْ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٞ مِّنۡهُمۡۖ وَقَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا سَٰحِرٞ كَذَّابٌ

Wọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: “Èyí ni òpìdán, òpùrọ́.”

أَجَعَلَ ٱلۡأٓلِهَةَ إِلَٰهٗا وَٰحِدًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عُجَابٞ

Ṣé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu.