38 : 34
وَلَقَدۡ فَتَنَّا سُلَيۡمَٰنَ وَأَلۡقَيۡنَا عَلَىٰ كُرۡسِيِّهِۦ جَسَدٗا ثُمَّ أَنَابَ
Dájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà).
Explanation & meanings · 1
- Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ṣe parọ́ ìyàwó gbígbà mọ́ Ànábì Dā’ūd - kí ọlà Allāhu máa bá a -, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe parọ́ pé aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú kan gba ìjọba lọ́wọ́ Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Irọ́ burúkú ni èyí. Ìṣe àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì ni irọ́ pípa mọ́ àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.