Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

يسٓ

يسٓ is chapter 36 of the Quran and has 83 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

83 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 36
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

يسٓ

Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡحَكِيمِ

(Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:1

إِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

(O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām).

تَنزِيلَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ

(Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run