Skip to content
يسٓ /

Ẹsẹ 45

36 : 45

Ẹsẹ 45 of يسٓ (36 : 45). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

يسٓ Àwọn Ẹsẹ 83
Súrà · يسٓ
Yorùbá · Mikail
36 : 45

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُواْ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيكُمۡ وَمَا خَلۡفَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ

(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín àti ohun tó wà lẹ́yìn yín nítorí kí A lè kẹ yín.”

Explanation & meanings · 2
  1. “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín”; ohun tí ó wà níwájú wọn ni àwọn àpẹ̀ẹrẹ irú ìyà àti ìparun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́ ṣíwájú wọn.
  2. “àti ohun tó wà lẹ́yìn yín”; ohun tí ó wà lẹ́yìn wọn ni ìyà ọjọ́ Àjíǹde, ìyà Iná tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́.