Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

فَاطِر

فَاطِر is chapter 35 of the Quran and has 45 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

45 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 35
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ جَاعِلِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُوْلِيٓ أَجۡنِحَةٖ مَّثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۚ يَزِيدُ فِي ٱلۡخَلۡقِ مَا يَشَآءُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ

Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Explanation & meanings · 1
  1. Àgbọ́yé òǹkà tí ó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 ni àgbọ́yé òǹkà tó tún jẹyọ nínú āyah yìí. Èyí túmọ̀ sí pé, alápá méjì wà nínú àwọn mọlāika, alápá mẹ́ta wà nínú wọn, alápá mẹ́rin sì wà nínú wọn. Alápá púpọ̀, tí apá rẹ̀ lé ní mẹ́rin, tún wà nínú wọn.

مَّا يَفۡتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحۡمَةٖ فَلَا مُمۡسِكَ لَهَاۖ وَمَا يُمۡسِكۡ فَلَا مُرۡسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dì í mọ́wọ́ (láti dá a dúró). Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ هَلۡ مِنۡ خَٰلِقٍ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ

Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كُذِّبَتۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ

Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ

Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (aṣ-ṣaetọ̄n) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ.