28 : 56
إِنَّكَ لَا تَهۡدِي مَنۡ أَحۡبَبۡتَ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ
Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
Explanation & meanings · 1
- “Hidāyah” túmọ̀ sí ìwọ̀nyí: (1) Ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn ’Islām, ṣíṣí ọkàn ẹ̀dá payá fún gbígba ẹ̀sìn ’Islām, fífi al-Ƙur’ān àti sunnah ṣàlàyé ìmọ̀nà sí ọ̀nà tààrà ’Islām àti títọ́ka ènìyàn sí ibì kan tàbí fífi ojú-ọ̀nà kan mọ ènìyàn.