“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”.
«صَلَاةٌ فِي مَسْجِدِي هَذَا خَيْرٌ مِنْ أَلْفِ صَلَاةٍ فِيمَا سِوَاهُ إِلَّا الْمَسْجِدَ الْحَرَامَ».
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun irun ti a ki ni mọsalasi rẹ, pe o lọla ni ẹsan ju ẹgbẹrun irun ti a ki lọ ni ibi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi aye, afi irun ti a ba ki ni mọsalasi ọwọ ni Makkah, oun lọla ju irun ti a ki ni mọsalasi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lọ.
...:
Adipele ẹsan fun irun ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ, ati ni mọsalasi ti Anabi.
Irun ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ loore ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún irun ti a ki ni eyi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi lọ.
Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (2/ 60) (1190).
Tira Sọhiihu ti Muslim (2/ 1012) (1394).
Àlékún (2)
فتح الباري (3/67).
البحر المحيط الثجاج في شرح صحيح الإمام مسلم بن الحجاج (24/ 684).
A tọ́ka sí nínú àwọn ìwé
4 Àwọn Ìwé- Ìwádìí àti ise Àlàyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn koko ọrọ nípa Hajj àti Umrah àti Ìṣàbẹ̀wò nibamu sí Al-Qur'an àti Sunnah.التحقيق والإيضاح لكثير من مسائل الحج والعمرة والزيارة - النسخة المعتمدة“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ (ni Makkah) ”[109].
- Àwọn ọla àti àwọn ẹkọ Masalasi Anọbi, àti àwọn ìdájọ ṣíṣe àbẹ̀wò sí saare Anabi (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) àti saare àwọn ọrẹ rẹ mejeeji (kí Ọlọhun yọnu si wọn).فضائل وآداب المسجد النبوي، وأحكام زيارة قبر النبي عليه الصلاة والسلام وقبري صاحبيه“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun ti a ki ni ibi ti o yatọ si i lọ, afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”[2].