Skip to content

"Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".

Lati ọdọ Abu Umaamah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣe khutubah ni hajj idagbere, o sọ pe:

"Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".

«اتَّقُوا اللَّهَ رَبَّكُمْ، وَصَلُّوا خَمْسَكُمْ، وَصُومُوا شَهْرَكُمْ، وَأَدُّوا زَكَاةَ أَمْوَالِكُمْ، وَأَطِيعُوا ذَا أَمْرِكُمْ تَدْخُلُوا جَنَّةَ رَبِّكُمْ».

Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe khutubah ni ọjọ 'Arafah, ni hajj idagbere, ni ọdun kẹwàá ninu hijira, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dagbere fun awọn eniyan nibẹ, O pa awọn eniyan patapata láṣẹ lati bẹru Oluwa wọn pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn ẹ̀kọ̀ Rẹ. Pe ki wọn maa ki awọn irun maraarun-un ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe wọn ni ọran-anyan ni ọsan ati alẹ. Pe ki wọn maa gba awẹ oṣu Ramadan. Pe ki wọn maa yọ saka awọn dukia fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ki wọn si ma ṣe ahun pẹlu rẹ. Pe ki wọn maa tẹle awọn ti Ọlọhun fi ṣe adari le wọn lori, yàtọ̀ si ibi ṣiṣẹ Ọlọhun, Ẹni ti o ba ṣe awọn nnkan ti a dárúkọ yìí, ẹsan rẹ ni wiwọ alujanna.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Awọn iṣẹ yii wa ninu awọn okunfa wiwọ alujanna.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sunanu ti Tirmidhiy (1/ 602) (616).

Tira Musnad ti Ahmad (36/ 486) (22161).

Àlékún (4)

شرح رياض الصالحين.

لابن عثيمين (1/ 534).

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (1/ 105).