Skip to content

«Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha».

Lati ọdọ Ubaadah ọmọ Saamit - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

«Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha».

«لَا صَلَاةَ لِمَنْ لَمْ يَقْرَأْ بِفَاتِحَةِ الكِتَابِ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju irun o le ni alaafia ayaafi pẹlu kika suuratul Faatiha, o si jẹ origun kan ninu awọn origun irun nibi gbogbo rakaha.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Nkankan o le dipo kika Faatiha yatọ si i pẹlu nini ikapa lati ka a.

Bibajẹ rakaha eleyii ti wọn o ka Faatiha ninu rẹ, lati ọdọ ẹni ti o finu-findọ ṣe e, ati alaimọkan ati onigbagbe; nitori pe dajudaju origun ni i, ati pe awọn origun o lee bọ lailai.

Kika Faatiha o maa bọ fun ero ẹyin nigba ti o ba ba imaamu ni rukuu.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 151) (756).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 295) (394).

Àlékún (4)

تيسير العلام.

للبسام (ص171).

تنبيه الأفهام.

لابن عثيمين (217).