27 : 88
وَتَرَى ٱلۡجِبَالَ تَحۡسَبُهَا جَامِدَةٗ وَهِيَ تَمُرُّ مَرَّ ٱلسَّحَابِۚ صُنۡعَ ٱللَّهِ ٱلَّذِيٓ أَتۡقَنَ كُلَّ شَيۡءٍۚ إِنَّهُۥ خَبِيرُۢ بِمَا تَفۡعَلُونَ
O sì máa rí àwọn àpáta, tí o lérò pé n̄ǹkan gbagidi tó dúró sojú kan náà ni, tí ó máa rin ìrìn ẹ̀ṣújò. (Ìyẹn jẹ́) iṣẹ́ Allāhu, Ẹni tí Ó ṣe gbogbo n̄ǹkan dáadáa. Dájúdájú Alámọ̀tán ni nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn ni pé, gbogbo àpáta máa rin ìrìn àrìntúká yángá, tó máa di pẹ̀tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣújò náà ṣe máa ń rìn, tó sì máa túká.