Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

النور

ﮤ

النور is chapter 24 of the Quran and has 64 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

64 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 24
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

سُورَةٌ أَنزَلۡنَٰهَا وَفَرَضۡنَٰهَا وَأَنزَلۡنَا فِيهَآ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖ لَّعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ

(Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe ìdájọ́ inú rẹ̀ ní òfin (dandan). A sì sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.

ٱلزَّانِيَةُ وَٱلزَّانِي فَٱجۡلِدُواْ كُلَّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا مِاْئَةَ جَلۡدَةٖۖ وَلَا تَأۡخُذۡكُم بِهِمَا رَأۡفَةٞ فِي دِينِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۖ وَلۡيَشۡهَدۡ عَذَابَهُمَا طَآئِفَةٞ مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Onísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì.

Explanation & meanings · 1
  1. Ọgọ́rùn-ún kòbókò àti ẹ̀wọ̀n ọdún kan tàbí ọgọ́rùn-ún kòbókò àti lílé kúrò nínú ìlú fún ọdún kan ni ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ‘akdu-nnikāh pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Àmọ́ lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà fún onísìná tí ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí.

ٱلزَّانِي لَا يَنكِحُ إِلَّا زَانِيَةً أَوۡ مُشۡرِكَةٗ وَٱلزَّانِيَةُ لَا يَنكِحُهَآ إِلَّا زَانٍ أَوۡ مُشۡرِكٞۚ وَحُرِّمَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Onísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin. A sì ṣe ìyẹn (sìná ṣíṣe) ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Explanation & meanings · 2
  1. Àwọn onímọ̀ pín sí mẹ́ta lórí ìtúmọ̀ āyah yìí nítorí pé, ìtúmọ̀ mẹ́ta tí ó ń padà síbi n̄ǹkan ẹyọ kan ni kalmọh “nikāh” ń túmọ̀ sí nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni fífẹ́ (ṣíṣe ìgbéyàwó), títi kálámù bọ inú ìgò tàdáà yálà ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tàbí ní ọ̀nà àìtọ́ àti ṣíṣe sìná (àgbèrè).
  2. Nítorí náà, “ìyẹn” nínú gbólóhùn yìí “A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” ń tọ́ka sí “zinā”. Ìyẹn ni pé, “A sì ṣe zinā ṣíṣe ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” Èyí sì ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ “lā yankihu” sí “kò níí ṣe sìná”.

وَٱلَّذِينَ يَرۡمُونَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَأۡتُواْ بِأَرۡبَعَةِ شُهَدَآءَ فَٱجۡلِدُوهُمۡ ثَمَٰنِينَ جَلۡدَةٗ وَلَا تَقۡبَلُواْ لَهُمۡ شَهَٰدَةً أَبَدٗاۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ

Àwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.

إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ̀sùn zinā lágbára púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó jẹ́ pé kòbókò ọgọrin ni ìjìyà tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí ẹni tí ó bá parọ́ zina mọ́ ẹlòmíìràn.