17 : 111
وَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلِيّٞ مِّنَ ٱلذُّلِّۖ وَكَبِّرۡهُ تَكۡبِيرَۢا
Kí o sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò sì ní ọ̀rẹ́ kan torí àìlágbára.” Gbé títóbi fún Un gan-an.
Explanation & meanings · 2
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Fātihah;1:2.
- Ìyẹn ni pé, mímú tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá mú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ kì í ṣe nítorí ìrànlọ́wọ́ wọn tàbí ìkúnlọ́wọ́ wọn, bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu gan-an ní Olùrànlọ́wọ́ wọn, Alágbára àti Olùborí lórí wọn.