Skip to content
الإسرَاء /

Ẹsẹ 110

17 : 110

Ẹsẹ 110 of الإسرَاء (17 : 110). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

الإسرَاء Àwọn Ẹsẹ 111
Súrà · الإسرَاء
Yorùbá · Mikail
17 : 110

قُلِ ٱدۡعُواْ ٱللَّهَ أَوِ ٱدۡعُواْ ٱلرَّحۡمَٰنَۖ أَيّٗا مَّا تَدۡعُواْ فَلَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَلَا تَجۡهَرۡ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتۡ بِهَا وَٱبۡتَغِ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلٗا

Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).” Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn.

Explanation & meanings · 1
  1. Pípe Allāhu tàbí ar-Rahmọ̄n tàbí èyíkéyìí nínú àwọn orúkọ Allāhu tí ó dára jùlọ, kò túmọ̀ sí fífa orúkọ kan nínú àwọn orúkọ Allāhu pẹ̀lú òǹkà púpọ̀ bíi sísọ pé Allāhu, Allāhu … tàbí ar-Rahmọ̄n, ar-Rahmọ̄n … Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìlànà àwọn onibid‘ah. Èyí tí ó tọ sunnah ni lílo àwọn orúkọ náà nínú gbólóhùn.