Skip to content

Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala "

Lati ọdọ Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:

Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala ". O n bẹ fun Bukhari: O sọ pe: "Ṣe aluwala ki o si fọ nnkan ọmọkunrin rẹ".

كُنْتُ رَجُلًا مَذَّاءً وَكُنْتُ أَسْتَحْيِي أَنْ أَسْأَلَ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِمَكَانِ ابْنَتِهِ فَأَمَرْتُ الْمِقْدَادَ بْنَ الْأَسْوَدِ فَسَأَلَهُ فَقَالَ: «يَغْسِلُ ذَكَرَهُ وَيَتَوَضَّأُ». وَلِلبُخَاريِّ: فَقَالَ: «تَوَضَّأْ وَاغْسِلْ ذَكَرَكَ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe atọ ireke- oun ni omi funfun ti kò ki ti o maa n fà tìkọ̀, o maa n jade lati inu nnkan ọmọkunrin nigba adun tabi ṣíwájú ibalopọ- maa n jáde lara oun lọpọlọpọ, Ko si mọ bi o ṣe maa ṣe pẹlu jijade rẹ, o wa tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; nitori pe o jẹ ọkọ Fatimah ọmọbìnrin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa tọrọ lọdọ Miqdad ọmọ Al-Aswad lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa ìyẹn, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Ki o fọ nnkan ọmọkunrin rẹ lẹyin naa ki o ṣe aluwala.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ọla ti o n bẹ fun Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i-, nigba ti itiju ko kọdi rẹ nibi gbigbe ibeere ju silẹ pẹlu alagata.

Nini ẹtọ yiyan ẹni kan lati lọ ba eeyan beere idajọ ẹsin.

Nini ẹtọ sísọ fun ọmọniyan nipa ara rẹ pẹlu nnkan ti o ba n ti i loju fun anfaani.

Jijẹ ẹgbin atọ ireke, ati jijẹ dandan fifọ ọ kuro ni ara ati aṣọ.

Jijade atọ ireke wa ninu awọn nnkan ti n ba aluwala jẹ.

Jijẹ dandan fifọ nnkan ọmọkunrin ati koropọn mejeeji nitori wiwa rẹ ninu hadiisi mii.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 62) (269).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 247) (303).

Àlékún (6)

الإلمام بشرح عمدة الأحكام.

لإسماعيل الأنصاري (1/ 39).

تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.

للبسام (ص53).

خلاصة الكلام شرح عمدة الأحكام.

لفيصل آل مبارك (ص29).