10 : 68
قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱلۡغَنِيُّۖ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنۡ عِندَكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭ بِهَٰذَآۚ أَتَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” - Mímọ́ ni fún Un. Òun ní Ọlọ́rọ̀. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. - Kò sí ẹ̀rí kan lọ́dọ̀ yín lórí èyí. Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣe àfitì ọ̀rọ̀ tí ẹ ò nímọ̀ rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?
Explanation & meanings · 1
- Ó rọrọ̀ tayọ bíbí ọmọ àti sísọ ẹnì kan di ọmọ.