Skip to content

Fi wọn silẹ, nitori pe dajudaju mo ti mejeeji bọ ọ ni mimọ ni

Lati ọdọ Al-Mughiirah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe.

Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni irin-ajo kan, ni mọ ba bẹrẹ lati bọ abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji, ni o wa sọ pe: «Fi wọn silẹ, nitori pe dajudaju mo ti mejeeji bọ ọ ni mimọ ni» ni o wa fi ọwọ pa mejeeji.

كُنْتُ مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِي سَفَرٍ، فَأَهْوَيْتُ لِأَنْزِعَ خُفَّيْهِ، فَقَالَ: «دَعْهُمَا، فَإِنِّي أَدْخَلْتُهُمَا طَاهِرَتَيْنِ» فَمَسَحَ عَلَيْهِمَا.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ni ọkan ninu awọn irin-ajo rẹ, ni o wa ṣe aluwala, Nigba ti o wa débi fifọ ẹsẹ mejeeji, Al- Mughiirah ọmọ Shu‘bah - ki Ọlọhun yọnu si i - na ọwọ rẹ mejeeji lati bọ nkan ti o wa ni ẹsẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni abọsẹsẹ alawọ lati fọ ẹsẹ rẹ mejeeji. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Fi mejeji silẹ ma bọ wọn, torí pé dajudaju mo ti ẹsẹ mi mejeeji bọ inu abọsẹsẹ alawọ mejeeji ti mo si wa lori imọra, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fi ọwọ pa abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji lati fi jirọ fifọ ẹsẹ mejeeji.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Jijẹ nǹkan ti a ṣe lofin pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji a maa ṣẹlẹ nibi ṣiṣe aluwala latara ẹgbin kekere, amọ wiwẹ fun ẹgbin nla ko si ibuyẹ kuro nibi fifọ ẹsẹ mejeeji.

Pipa o maa jẹ ẹẹkan pẹlu mimu ọwọ ti o ti rin fun omi lọ bọ lori abọsẹsẹ alawọ yatọ si isalẹ rẹ.

Wọn ṣe ni majẹmu fun pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji ki wiwọ rẹ o jẹ lẹyin aluwala ti o pe ti yio fọ ẹsẹ rẹ mejeeji ninu rẹ, ati pe ki abọsẹsẹ alawọ naa o mọ, ki o si tun bo aaye ọranyan nibi ẹsẹ, ki pipa a na o waye nibi ẹgbin kekere, ki o ma jẹ nibi janaba tabi nkan ti o le sọ iwẹ di dandan, ati pe ki pipa naa o maa waye laarin asiko ti a là kalẹ ninu shariah oun naa ni ọjọ kan pẹlu oru kan fun onile ati ọjọ mẹta pẹlu oru rẹ fun arinrin-ajo.

Wọn o fi jọ ibọsẹ alawọ mejeeji gbogbo nkan ti o ba ti le bo ẹsẹ bi ibọsẹ olowuu ati nkan ti o yatọ si i, nitori naa o lẹtọọ lati fi ọwọ pa a.

Didaa iwa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ikọnilẹkọọ rẹ, latari pe o kọ fun Al-Mughiirah lati bọ ibọsẹ alawọ mejeeji, ti o si tun ṣe alaye idi rẹ fun un: Wipe dajudaju o wọ mejeeji ni mimọ; ki ẹmi rẹ le balẹ, ki o si tun mọ idajọ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 52) (206).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 230) (274).

Àlékún (6)

تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.

لعبد الله البسام (ص50).

الإلمام بشرح عمدة الأحكام.

لإسماعيل الأنصاري (1/ 36).

خلاصة الكلام شرح عمدة الأحكام.

لفيصل آل مبارك (ص27).