6 : 52
وَلَا تَطۡرُدِ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ مَا عَلَيۡكَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَمَا مِنۡ حِسَابِكَ عَلَيۡهِم مِّن شَيۡءٖ فَتَطۡرُدَهُمۡ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.
Explanation & meanings · 1
- Āyah yìí ń sọ nípa àwọn Sọhābah tí wọ́n jẹ́ tálíkà pọ́nńbélé, gẹ́gẹ́ bí āyah 53 tí ó tẹ̀lé āyah yìí ṣe fi hàn, wọn kì í ṣe sūfī gẹ́gẹ́ bí àwọn òpùrọ́ kan ṣe lérò.