Skip to content
الأنعَام /

Ẹsẹ 121

6 : 121

Ẹsẹ 121 of الأنعَام (6 : 121). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

الأنعَام Àwọn Ẹsẹ 165
Súrà · الأنعَام
Yorùbá · Mikail
6 : 121

وَلَا تَأۡكُلُواْ مِمَّا لَمۡ يُذۡكَرِ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ وَإِنَّهُۥ لَفِسۡقٞۗ وَإِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِهِمۡ لِيُجَٰدِلُوكُمۡۖ وَإِنۡ أَطَعۡتُمُوهُمۡ إِنَّكُمۡ لَمُشۡرِكُونَ

Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa. Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n, wọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.

Explanation & meanings · 1
  1. Méjì ni ẹran tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa. Ìkíní: ẹran tí wọ́n fi orúkọ mìíràn yàtọ̀ sí orúkọ Allāhu pa, èèwọ̀ ni. Ìkejì: ẹran tí mùsùlùmí pa, àmọ́ tí ó gbàgbé láti fi orúkọ Allāhu pa á, wọ́n ṣàmójú kúrò fún un, ẹ̀tọ́ sì ni ẹran náà. Àmọ́ ìyapa-ẹnu wà lórí jíjẹ ẹran náà bí ó bá jẹ́ pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàì fi orúkọ Allāhu pa á ni.