Skip to content
المَائدة /

Ẹsẹ 93

5 : 93

Ẹsẹ 93 of المَائدة (5 : 93). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

المَائدة Àwọn Ẹsẹ 120
Súrà · المَائدة
Yorùbá · Mikail
5 : 93

لَيۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جُنَاحٞ فِيمَا طَعِمُوٓاْ إِذَا مَا ٱتَّقَواْ وَّءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ ثُمَّ ٱتَّقَواْ وَّءَامَنُواْ ثُمَّ ٱتَّقَواْ وَّأَحۡسَنُواْۚ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere nípa ohun tí wọ́n jẹ (nínú ouńjẹ ṣíwájú òfin) nígbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ́rù Allāhu, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.

Explanation & meanings · 1
  1. Mímú ìbẹ̀rù Allāhu àti ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ wá ní àsọtúnsọ nínú āyah yìí ń tọ́ka sí lílékún ní ìbẹ̀rù Allāhu, ìgbàgbọ́ òdodo àti iṣẹ́ rere.