Skip to content
المَائدة /

Ẹsẹ 32

5 : 32

Ẹsẹ 32 of المَائدة (5 : 32). This page carries the verse in the Uthmani script with a translation of its meaning, at a stable URL that can be cited on its own.

المَائدة Àwọn Ẹsẹ 120
Súrà · المَائدة
Yorùbá · Mikail
5 : 32

مِنۡ أَجۡلِ ذَٰلِكَ كَتَبۡنَا عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَنَّهُۥ مَن قَتَلَ نَفۡسَۢا بِغَيۡرِ نَفۡسٍ أَوۡ فَسَادٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ ٱلنَّاسَ جَمِيعٗا وَمَنۡ أَحۡيَاهَا فَكَأَنَّمَآ أَحۡيَا ٱلنَّاسَ جَمِيعٗاۚ وَلَقَدۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡأَرۡضِ لَمُسۡرِفُونَ

Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀.

Explanation & meanings · 1
  1. Ìbàjẹ́ ṣíṣe lórí ilẹ̀ pé oríṣiríṣi. Nítorí náà, àwọn ìbàjẹ́ kan wà tí ó jẹ́ pé pípa ọ̀daràn ni ìjìyà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé, àwọn ìbàjẹ́ kan wà tí ìjìyà wọn kò wọ ipò pípa ọ̀daràn.