Skip to content
Àkójọ Àwọn Súrà /

الجاثِية

الجاثِية is chapter 45 of the Quran and has 37 verses. This page presents it in full in the Uthmani script, with a verse-by-verse translation of its meaning.

37 Àwọn Ẹsẹ Nọ́ńbà Súrà 45
Lọ sí ẹsẹ
Yorùbá · Mikail
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

حمٓ

Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ

Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.

إِنَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àwọn àmì wà (nínú wọn) fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

وَفِي خَلۡقِكُمۡ وَمَا يَبُثُّ مِن دَآبَّةٍ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ

Àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá yín àti ohun tí Allāhu ń fọ́nká (sórí ilẹ̀) nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.

Explanation & meanings · 1
  1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:164.

وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن رِّزۡقٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ

(Nínú) ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní arísìkí, tí Ó ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tó ti kú àti ìyípadà atẹ́gùn, àwọn àmì tún wà (nínú wọn) fún ìjọ tó ní làákàyè.