Skip to content

Ki ni idi ti wọn ko fi gba hadisi kankan ti o da lori bibajẹ aluwala pẹlu nnkan ti o n san yẹn wá láti ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tòun ti bi o ṣe jẹ pe awọn sọhaba lobinrin maa n ṣe ojúkòkòrò láti béèrè nipa idajọ awọn alamọri ẹsin wọn?

السؤال

Ibeere akọkọ:

س43: ما العلة في أنه لم ينقل عن الرسول ﷺ حديثٌ يدلّ على نقض الوضوء بذلك السائل، مع أن الصحابيات كن يحرصن على الاستفتاء في أمور دينهن؟

الجواب

Idahun akọkọ:

Nitori pe nnkan ti o n sàn yẹn kii ṣe gbogbo obìnrin ni o maa n ṣẹlẹ si.

ﺟ43: لأن السائل لا يأتي كل امرأةٍ.