Skip to content

"Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu".

Lati ọdọ 'Adiyyu ọmọ Haatim, lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:

"Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu".

«الْيَهُودُ مَغْضُوبٌ عَلَيْهِمْ، وَالنَّصَارَى ضُلَّالٌ».

Tirmisiy ni o gba a wa
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju awọn Juu ni ìjọ kan ti Ọlọhun binu si wọn, nitori pe wọn mọ ododo wọn ko si ṣiṣẹ pẹlu rẹ. Ati pe awọn Nasara ni ìjọ ẹni anu; nitori pe wọn ṣe iṣẹ laini imọ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Idapọ laaarin imọ ati iṣẹ jẹ igbala kuro ni oju ọna awọn ti a binu si ati awọn ẹni anu.

Ikilọ kuro ni oju ọna awọn Juu ati Nasara, ati didunnimọ oju ọna taara ti o ṣe pe oun ni Isilaamu.

Olukuluku ninu awọn Juu ati Nasara ni ẹni anu ti a binu si, ṣùgbọ́n eyi ti o jẹ ẹsa ju ninu awọn iroyin awọn Juu ni ibinu, ti eyi ti o jẹ ẹsa ju ninu awọn iroyin awọn Nasara ni anu.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sunanu ti Tirmidhiy (5/ 71) (2954).

Àlékún (3)

النهاية في غريب الحديث و الأثر ( ص 548).

المنهل العذب المورود (5/250).

البحر المحيط الثجاج (9/248).