Skip to content

«Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:

«Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».

«المُسْلِمُ مَنْ سَلِمَ المُسْلِمُونَ مِنْ لِسَانِهِ وَيَدِهِ، وَالمُهَاجِرُ مَنْ هَجَرَ مَا نَهَى اللَّهُ عَنْهُ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe dajudaju musulumi ti Isilaamu rẹ pe oun ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ, ko nii bu wọn, ko si nii ṣepe fun wọn, ko si nii sọ ọrọ wọn lẹyin, ko si nii maa fi ahọn rẹ tan èyíkéyìí ninu awọn iran ṣuta ka laarin wọn, Ti wọn si tun la ni ọwọ rẹ, ko si nii tayọ ẹnu-ala si wọn, ko si nii gba awọn dukia wọn ni ọna aitọ, ati nkan ti o jọ ìyẹn, Ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o gbe nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe leewọ jusilẹ.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Isilaamu o le pe ayaafi pẹlu àìfi ṣuta kan ẹlòmíràn, o jẹ èyí tí a fi oju ri ni abi èyí tí a o le ni ìmọ̀lára rẹ.

Wọn ṣa ahọn ati ọwọ lẹsa pẹlu didarukọ wọn; latari pipọ awọn aṣiṣe wọn ati awọn inira wọn, ati pe dajudaju ọdọ wọn ni ọpọlọpọ aburu ti maa n wa.

Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbe awọn ẹṣẹ silẹ ati ṣíṣe nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pa lasẹ.

Ẹni ti o ni ọla julọ ninu awọn musulumi ni ẹni ti o pe awọn iwọ Ọlọhun ati awọn iwọ awọn musulumi.

Itayọ aala le jẹ ọrọ tabi iṣe.

Hijrah ti o pe oun ni yiyan nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe ni eewọ lodi.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 11) (10).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 65) (40).

Àlékún (6)

نزهة المتقين شرح رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (1/ 236).

شرح رياض الصالحين.

لابن عثيمين (2/ 511).

بهجة الناظرين شرح رياض الصالحين.

لسليم الهلالي (1/ 306).