9 : 106
وَءَاخَرُونَ مُرۡجَوۡنَ لِأَمۡرِ ٱللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمۡ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيۡهِمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná títí àṣẹ Allāhu máa fi dé; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Explanation & meanings · 2
- Ìyẹn, àwọn tó ṣàì lọ sógun, àmọ́ tí wọn kò mú àwáwí irọ́ wá.
- Àṣẹ náà dé nínú āyah 118 níwájú.