3 : 72
وَقَالَت طَّآئِفَةٞ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ ءَامِنُواْ بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَجۡهَ ٱلنَّهَارِ وَٱكۡفُرُوٓاْ ءَاخِرَهُۥ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Igun kan nínú àwọn onítírà wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām).
Explanation & meanings · 1
- Ìyẹn ni pé, wọ́n ń gba Islām láti kóbá àwọn ènìyàn nípa sísọ ohun tí kì í ṣe òtítọ́ nípa Islām.